4 Wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé,+ gbogbo ọmọ ogun sì sá gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba lóru, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; ọba sì sá gba ọ̀nà Árábà.+
5 Màá fi gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun iyebíye rẹ̀ àti gbogbo ìṣúra àwọn ọba Júdà lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.+ Wọ́n á gba tọwọ́ wọn, wọ́n á mú wọn, wọ́n á sì kó wọn lọ sí Bábílónì.+