ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 20:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí wọ́n máa kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé* rẹ àti gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní yìí lọ sí Bábílónì.+ Kò ní ku nǹkan kan,’ ni Jèhófà wí.

  • 2 Àwọn Ọba 24:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí ìlú náà nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dó tì í.

  • 2 Àwọn Ọba 24:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba jáde kúrò.+ Gbogbo nǹkan èlò wúrà tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà+ ni ó gé sí wẹ́wẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́.

  • 2 Àwọn Ọba 25:13-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó àwọn bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 14 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn ìkóná àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà+ ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà+ ṣe.

  • Ìdárò 1:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Elénìní ti kó gbogbo ìṣúra rẹ̀.+

      Nítorí ìṣojú rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú ibi mímọ́ rẹ̀,+

      Àwọn tí o pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe wá sínú ìjọ rẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́