-
Ìsíkíẹ́lì 8:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jọ̀ọ́ gbójú sókè kí o wo àríwá.” Torí náà, mo wo àríwá, mo sì rí ère* owú náà ní àríwá ẹnubodè pẹpẹ. 6 Ó sì sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ṣé o rí ohun ìríra tó burú jáì tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe níbí,+ tó mú kí n jìnnà sí ibi mímọ́ mi?+ O máa rí àwọn ohun tó ń ríni lára tó tún burú ju èyí lọ.”
-