-
2 Kíróníkà 33:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+
-
-
2 Kíróníkà 36:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Gbogbo olórí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòótọ́ tó bùáyà, wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe, wọ́n sì sọ ilé Jèhófà di ẹlẹ́gbin,+ èyí tó ti yà sí mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.
-
-
Jeremáyà 7:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ṣé ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè ti wá di ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí lójú yín ni?+ Èmi fúnra mi ti rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe,” ni Jèhófà wí.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 8:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, mo wọlé, mo wò ó, mo sì rí oríṣiríṣi àwòrán ohun tó ń rákò àti ẹranko tó ń kóni nírìíra+ àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin* ilé Ísírẹ́lì;+ wọ́n gbẹ́ ẹ sí ara ògiri káàkiri. 11 Àádọ́rin (70) ọkùnrin lára àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì dúró níwájú wọn, Jasanáyà ọmọ Ṣáfánì+ sì wà lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú àwo tùràrí rẹ̀ dání, èéfín tùràrí tó ní òórùn dídùn sì ń gòkè lọ.+
-