52 Wọ́n máa dó tì ọ́, wọ́n máa sé ọ mọ́ inú gbogbo ìlú* rẹ, jákèjádò ilẹ̀ rẹ títí àwọn ògiri rẹ tó ga, tí o fi ṣe odi tí o gbẹ́kẹ̀ lé fi máa wó lulẹ̀. Àní ó dájú pé wọ́n máa dó tì ọ́ nínú gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ.+
24 Wò ó! Àwọn èèyàn ti wá mọ òkìtì láti dó ti ìlú náà kí wọ́n lè gbà á,+ ó sì dájú pé idà+ àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn*+ yóò mú kí ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Kálídíà tó ń bá a jà; gbogbo ohun tí o sọ ló ti ṣẹ bí ìwọ náà ṣe rí i báyìí.