ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 5:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Gbàrà tí àwọn tó ń fun kàkàkí àti àwọn akọrin bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà, tí wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ohùn tó ṣọ̀kan, tí ìró kàkàkí àti síńbálì pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin míì ń dún sókè bí wọ́n ṣe ń yin Jèhófà, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì wà títí láé,”+ ni ìkùukùu+ bá kún inú ilé náà, ìyẹn ilé Jèhófà.

  • Ẹ́sírà 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn kọrin,+ wọ́n ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, “nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí Ísírẹ́lì sì wà títí láé.”+ Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn kígbe sókè láti yin Jèhófà nítorí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀.

  • Sáàmù 106:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 106 Ẹ yin Jáà!*

      Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+

      Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

  • Àìsáyà 12:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa sọ pé:

      “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,

      Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+

      Ẹ kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.+

  • Míkà 7:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ta ló dà bí rẹ, Ọlọ́run,

      Tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó sì ń gbójú fo ìṣìnà+ àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀?+

      Kò ní máa bínú lọ títí láé,

      Torí inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́