26 Àwọn èèyàn á sì wá láti àwọn ìlú Júdà àti láti àyíká Jerúsálẹ́mù àti láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ + àti láti àwọn agbègbè olókè àti láti Négébù. Wọ́n á máa mú odindi ẹbọ sísun + àti ẹbọ+ àti ọrẹ ọkà+ àti oje igi tùràrí wá, wọ́n á sì máa mú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà.+