-
Jeremáyà 42:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Gbogbo àwọn tí ó fi dandan lé e pé àwọn yóò lọ máa gbé ní Íjíbítì ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa. Kò sí ẹnì kankan tó máa sá àsálà tàbí tó máa la àjálù tí màá mú bá wọn já.”’
18 “Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Bí mo ṣe da ìbínú mi àti ìrunú mi sórí àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,+ bẹ́ẹ̀ ni màá da ìrunú mi sórí yín tí ẹ bá lọ sí Íjíbítì, ẹ ó sì di ẹni ègún àti ohun àríbẹ̀rù, ẹni ìfiré àti ẹni ẹ̀gàn,+ ẹ kò sì ní rí ibí yìí mọ́.’
-