-
2 Àwọn Ọba 25:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ keje oṣù náà, ìyẹn ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 9 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba+ pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù;+ ó tún sun ilé gbogbo àwọn ẹni ńlá.+ 10 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+
-
-
2 Kíróníkà 34:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀,+ ìyẹn gbogbo ègún tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé+ tí wọ́n kà níwájú ọba Júdà. 25 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa tú jáde bí iná sórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+
-
-
2 Kíróníkà 36:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.
17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+
-