21 Màá sì fi Sedekáyà ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí wọn* àti lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì+ tó ṣígun kúrò lọ́dọ̀ yín.’+
5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé wọn, wọ́n sì bá Sedekáyà ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò.+ Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ ibẹ̀ ló sì ti dá a lẹ́jọ́.