13 “‘Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Lẹ́yìn ogójì (40) ọdún, èmi yóò pa dà kó àwọn ará Íjíbítì jọ láti àárín àwọn èèyàn tí wọ́n tú ká sí;+ 14 Èmi yóò mú àwọn ẹrú Íjíbítì pa dà wá sí ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ ilẹ̀ tí wọ́n ti wá, wọ́n á sì di ìjọba tí kò já mọ́ nǹkan kan níbẹ̀.