19 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, la ọ̀nà méjì tí idà ọba Bábílónì yóò gbà wá. Ilẹ̀ kan náà ni méjèèjì yóò ti wá, kí o sì fi àmì sí ibi tí ọ̀nà náà ti pínyà lọ sí ìlú méjèèjì. 20 La ọ̀nà kan tí idà náà máa gbà wọ Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì láti bá a jà, kí ọ̀nà kejì sì wọ Jerúsálẹ́mù+ tí odi yí ká, ní Júdà.