12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+
11 A ó sì mú kí àwọn èèyàn Júdà àti ti Ísírẹ́lì ṣọ̀kan,+ wọ́n á yan olórí fún ara wọn, wọ́n á sì jáde kúrò ní ilẹ̀ náà, nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ náà máa jẹ́ ní Jésírẹ́lì.+