-
Jeremáyà 10:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà,
Tí gbogbo agbo ẹran wọn sì fi tú ká.”+
-
-
Jeremáyà 23:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń bójú tó àwọn èèyàn mi nìyí: “Ẹ ti tú àwọn àgùntàn mi ká, ẹ sì ń fọ́n wọn ká ṣáá, ẹ kò sì tọ́jú wọn.”+
“Torí náà màá fìyà jẹ yín nítorí ìwà ibi yín,” ni Jèhófà wí.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 34:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àwọn àgùntàn mi ń rìn kiri lórí gbogbo òkè ńlá àti lórí gbogbo òkè kéékèèké; àwọn àgùntàn mi fọ́n ká sí gbogbo ayé, kò sì sí ẹni tó ń wá wọn kiri tàbí tó ń béèrè ibi tí wọ́n wà.
-