ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 28:52
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 52 Wọ́n máa dó tì ọ́, wọ́n máa sé ọ mọ́ inú gbogbo ìlú* rẹ, jákèjádò ilẹ̀ rẹ títí àwọn ògiri rẹ tó ga, tí o fi ṣe odi tí o gbẹ́kẹ̀ lé fi máa wó lulẹ̀. Àní ó dájú pé wọ́n máa dó tì ọ́ nínú gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ.+

  • 2 Àwọn Ọba 25:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ Ó dó tì í, ó mọ òkìtì yí i ká,+ 2 wọ́n sì dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkànlá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà.

  • Àìsáyà 29:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Màá pàgọ́ yí ọ ká,

      Màá ṣe ọgbà láti dó tì ọ́,

      Màá sì ṣe àwọn ohun tí màá fi gbógun tì ọ́.+

  • Jeremáyà 39:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 39 Ní ọdún kẹsàn-án Sedekáyà ọba Júdà, ní oṣù kẹwàá, Nebukadinésárì* ọba Bábílónì àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dó tì í.+

  • Ìsíkíẹ́lì 4:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 “Ìwọ ọmọ èèyàn, gbé bíríkì kan, kí o sì gbé e síwájú rẹ. Ya àwòrán Jerúsálẹ́mù sórí rẹ̀. 2 Dó tì í,+ fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká,+ mọ òkìtì láti dó tì í,+ pàgọ́ yí i ká, kí o sì gbé àwọn igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri+ yí i ká.

  • Ìsíkíẹ́lì 21:21, 22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Torí ọba Bábílónì dúró ní oríta náà, níbi tí ọ̀nà ti pín sí méjì, kó lè woṣẹ́. Ó mi àwọn ọfà. Ó wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà* rẹ̀; ó fi ẹ̀dọ̀ woṣẹ́. 22 Nígbà tó woṣẹ́, ohun tó rí ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ darí wọn sí Jerúsálẹ́mù, pé kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri, kí wọ́n pàṣẹ láti pa ọ̀pọ̀, kí wọ́n kéde ogun, kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri ti àwọn ẹnubodè, kí wọ́n mọ òkìtì yí i ká láti dó tì í, kí wọ́n sì fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́