48 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà, àwọn ni: pẹpẹ+ wúrà; tábìlì wúrà+ tí wọ́n á máa kó búrẹ́dì àfihàn sí; 49 àwọn ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe, márùn-ún lápá ọ̀tún àti márùn-ún lápá òsì níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún; àwọn ìtànná òdòdó,+ àwọn fìtílà àti àwọn ìpaná tí a fi wúrà ṣe;+