-
Jeremáyà 5:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Wò ó, màá mú orílẹ̀-èdè kan láti ibi tó jìnnà wá bá yín, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,”+ ni Jèhófà wí.
“Orílẹ̀-èdè tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni.
-
-
Jeremáyà 25:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Màá ránṣẹ́ pe gbogbo ìdílé tó wà ní àríwá,”+ ni Jèhófà wí, “màá ránṣẹ́ sí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí+ àti àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ Màá pa wọ́n run pátápátá, màá sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti ohun àrísúfèé àti ibi àwókù títí láé.
-