9 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: “Mo ti rí i pé alágídí* ni àwọn èèyàn yìí.+10 Ní báyìí, fi mí sílẹ̀, màá fi ìbínú mi tó ń jó bí iná pa wọ́n run, kí o sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá dípò wọn.”+
14 “Ní tìrẹ,* má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn yìí. Má sì sunkún nítorí wọn tàbí kí o gbàdúrà fún wọn,+ torí mi ò ní fetí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń ké pè mí nígbà àjálù wọn.