ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 40:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ó mú igi láti fi ṣe ọrẹ,+

      Igi tí kò ní jẹrà.

      Ó wá oníṣẹ́ ọnà tó já fáfá,

      Láti ṣe ère gbígbẹ́ tí kò ní ṣubú.+

  • Àìsáyà 44:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ẹnì kan wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ̀ ni kó máa gé igi kédárì lulẹ̀.

      Ó mú oríṣi igi kan, ìyẹn igi ràgàjì,*

      Ó sì jẹ́ kó di igi ńlá láàárín àwọn igi igbó.+

      Ó gbin igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì, òjò sì mú kó dàgbà.

      15 Ó wá di ohun tí èèyàn lè fi dáná.

      Ó mú lára rẹ̀, ó sì fi yáná;

      Ó dá iná, ó sì yan búrẹ́dì.

      Àmọ́ ó tún ṣe ọlọ́run kan, ó sì ń sìn ín.

      Ó fi ṣe ère gbígbẹ́, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.+

  • Àìsáyà 45:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ẹ kóra jọ, kí ẹ sì wá.

      Ẹ jọ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin tí ẹ yè bọ́ látinú àwọn orílẹ̀-èdè.+

      Wọn ò mọ nǹkan kan, àwọn tó ń gbé ère gbígbẹ́ kiri,

      Tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbà wọ́n.+

  • Hábákúkù 2:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Kí ni àǹfààní ère,

      Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ?

      Kí ni àǹfààní ère onírin* àti olùkọ́ èké,

      Tí ẹni tó ṣe é bá tiẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e,

      Tó ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí, tí kò lè sọ̀rọ̀?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́