6 Àwọn kan wà tó ń kó wúrà jáde yàlàyòlò látinú àpò wọn;
Wọ́n ń wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n.
Wọ́n gba oníṣẹ́ irin síṣẹ́, ó sì fi ṣe ọlọ́run.+
Wọ́n wá wólẹ̀, àní, wọ́n jọ́sìn rẹ̀.+
7 Wọ́n gbé e sí èjìká wọn,+
Wọ́n gbé e, wọ́n sì fi sí àyè rẹ̀, ṣe ló kàn dúró síbẹ̀.
Kì í kúrò ní àyè rẹ̀.+
Wọ́n ké sí i, àmọ́ kò dáhùn;
Kò lè gba ẹnikẹ́ni nínú wàhálà.+