ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 18:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 “‘Ẹ má fi èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí sọ ara yín di aláìmọ́, torí gbogbo àwọn nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fẹ́ lé kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.+

  • Nọ́ńbà 35:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 “‘Ẹ má sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di ẹlẹ́gbin, torí ẹ̀jẹ̀ máa ń sọ ilẹ̀+ di ẹlẹ́gbin, kò sì sí ètùtù fún ẹ̀jẹ̀ tí ẹnì kan ta sórí ilẹ̀ àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni náà tó ta á sílẹ̀.+

  • Sáàmù 78:58
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 58 Wọ́n ń fi àwọn ibi gíga wọn mú un bínú ṣáá,+

      Wọ́n sì fi àwọn ère gbígbẹ́ wọn mú kí ìbínú rẹ̀ ru.*+

  • Sáàmù 106:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+

      Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn

      Tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì;+

      Ilẹ̀ náà sì di ẹlẹ́gbin nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.

  • Jeremáyà 16:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, màá san ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó yẹ wọ́n nítorí àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+

      Nítorí wọ́n ti fi àwọn ère aláìlẹ́mìí* ti òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́

      Wọ́n sì ti fi àwọn ohun ìríra wọn kún inú ogún mi.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́