5 Wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì láti sun àwọn ọmọ wọn nínú iná bí odindi ẹbọ sísun sí Báálì,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ tàbí sọ nípa rẹ̀, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.”’*+
15 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Wò ó, màá mú gbogbo àjálù tí mo sọ nípa rẹ̀ wá sórí ìlú yìí àti sórí gbogbo ìlú tó yí i ká, nítorí wọ́n ti ya alágídí,* wọn kò sì ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi.’”+