35 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì, tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná fún Mólékì,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ fún wọn,+ tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí pé kí wọ́n ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀ láti mú kí Júdà dẹ́ṣẹ̀.’