ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 7:48-50
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 48 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà, àwọn ni: pẹpẹ+ wúrà; tábìlì wúrà+ tí wọ́n á máa kó búrẹ́dì àfihàn sí; 49 àwọn ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe, márùn-ún lápá ọ̀tún àti márùn-ún lápá òsì níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún; àwọn ìtànná òdòdó,+ àwọn fìtílà àti àwọn ìpaná* tí a fi wúrà ṣe;+ 50 àwọn bàsíà, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà,+ àwọn abọ́, àwọn ife+ àti àwọn ìkóná+ tí á fi ògidì wúrà ṣe; ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé inú lọ́hùn-ún,+ ìyẹn, Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti ihò àwọn ilẹ̀kùn ilé tẹ́ńpìlì+ tí a fi wúrà ṣe.

  • Ẹ́sírà 1:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ọba Kírúsì tún kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà jáde, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù, tó sì kó sínú ilé ọlọ́run rẹ̀.+

  • Dáníẹ́lì 5:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Nígbà tí wáìnì ń pa Bẹliṣásárì, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà tí Nebukadinésárì bàbá rẹ̀ kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá,+ kí ọba àti àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì, àwọn wáhàrì* rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ onípò kejì lè fi wọ́n mutí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́