-
Jeremáyà 39:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé wọn, wọ́n sì bá Sedekáyà ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò.+ Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ ibẹ̀ ló sì ti dá a lẹ́jọ́. 6 Ọba Bábílónì ní kí wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀ ní Ríbúlà, ọba Bábílónì sì ní kí wọ́n pa gbogbo èèyàn pàtàkì Júdà.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é kó lè mú un wá sí Bábílónì.+
-
-
Jeremáyà 52:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì, ó sì dá a lẹ́jọ́. 10 Ọba Bábílónì pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀, ó sì tún pa gbogbo àwọn ìjòyè Júdà níbẹ̀ ní Ríbúlà. 11 Lẹ́yìn náà, ọba Bábílónì fọ́ ojú Sedekáyà,+ ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó mú un wá sí Bábílónì, ó sì fi í sẹ́wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.
-