6 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa wẹ ọkàn rẹ mọ́* àti ọkàn ọmọ+ rẹ, kí o lè fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa wà láàyè.+
33 “Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,” ni Jèhófà wí. “Màá fi òfin mi sínú wọn,+ inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+