ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 51:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Bábílónì jẹ́ ife wúrà ní ọwọ́ Jèhófà;

      Ó mú kí gbogbo ayé mu àmupara.

      Àwọn orílẹ̀-èdè ti mu nínú wáìnì rẹ̀ ní àmuyó;+

      Ìdí nìyẹn tí orí àwọn orílẹ̀-èdè fi dà rú.+

  • Ìdárò 4:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Máa yọ̀ kí inú rẹ sì máa dùn, ìwọ ọmọbìnrin Édómù,+ bí o ṣe ń gbé ní ilẹ̀ Úsì.

      Àmọ́ wọ́n á gbé ife náà fún ìwọ pẹ̀lú,+ wàá mu àmupara, wàá sì tú ara rẹ sí ìhòòhò.+

  • Ìsíkíẹ́lì 23:32-34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

      ‘Ìwọ yóò mu nínú ife ẹ̀gbọ́n rẹ, ife tí inú rẹ̀ jìn, tó sì fẹ̀.+

      Wọ́n á fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà, èyí tó kún inú ife náà.+

      33 Ìwọ yóò mu àmuyó, ìbànújẹ́ yóò sì bò ọ́,

      Wàá mu látinú ife ìbẹ̀rù àti ti ahoro,

      Ife Samáríà ẹ̀gbọ́n rẹ.

      34 Ìwọ yóò mu nínú rẹ̀, ìwọ yóò mu ún gbẹ,+ wàá sì máa họ àpáàdì rẹ̀ jẹ,

      Ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ ya.

      “Torí èmi alára ti sọ̀rọ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’

  • Náhúmù 3:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Gbogbo ẹni tó bá rí ọ máa sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+ á sì sọ pé,

      ‘Nínéfè ti di ahoro!

      Ta ló máa bá a kẹ́dùn?’

      Ibo ni màá ti rí àwọn olùtùnú fún ọ?

  • Náhúmù 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ìwọ náà á mutí yó;+

      Wàá lọ fara pa mọ́.

      Wàá sì wá ibi ààbò lọ́dọ̀ ọ̀tá rẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́