-
2 Kíróníkà 36:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́, ńlá àti kékeré pẹ̀lú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba àti ti àwọn ìjòyè rẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló kó wá sí Bábílónì.+
-
-
Jeremáyà 52:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù + àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 18 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́,+ àwọn ife+ àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì.
-