8 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Néhúṣítà ọmọ Élínátánì láti Jerúsálẹ́mù.
27 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jèhóákínì+ ọba Júdà ti wà ní ìgbèkùn, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù náà, Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tó jọba, dá Jèhóákínì ọba Júdà sílẹ̀* lẹ́wọ̀n.+