-
2 Kíróníkà 36:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* Ọba Nebukadinésárì ní kí wọ́n lọ mú un wá sí Bábílónì+ pẹ̀lú àwọn ohun iyebíye tó wà ní ilé Jèhófà.+ Bákan náà, ó fi Sedekáyà arákùnrin bàbá rẹ̀ jọba lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+
11 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 12 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wòlíì Jeremáyà,+ ẹni tó ń sọ ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un.
-