8 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Néhúṣítà ọmọ Élínátánì láti Jerúsálẹ́mù.
24 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí, ‘kódà bí Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá tiẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni màá ti yọ ọ́ kúrò!