ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 36:20, 21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ó mú àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà lẹ́rú, ó kó wọn lọ sí Bábílónì,+ wọ́n sì di ìránṣẹ́ òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí ìjọba* Páṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso,+ 21 kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ lè ṣẹ,+ títí ilẹ̀ náà fi san àwọn sábáàtì rẹ̀ tán.+ Ní gbogbo ọjọ́ tó fi wà ní ahoro, ó ń pa sábáàtì rẹ̀ mọ́, kí àádọ́rin (70) ọdún lè pé.+

  • Ẹ́sírà 1:1-3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 1 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé:

      2 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù,+ tó wà ní Júdà. 3 Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó lọ sí Jerúsálẹ́mù tó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́, òun ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ilé rẹ̀ wà ní Jerúsálẹ́mù.*

  • Dáníẹ́lì 9:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi òye mọ̀ látinú ìwé,* iye ọdún tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà pé Jerúsálẹ́mù fi máa wà ní ahoro,+ ìyẹn àádọ́rin (70) ọdún.+

  • Sekaráyà 1:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Torí náà, áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí o tó ṣàánú Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà+ tí o ti bínú sí fún àádọ́rin (70) ọdún báyìí?”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́