-
2 Kíróníkà 36:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ó mú àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà lẹ́rú, ó kó wọn lọ sí Bábílónì,+ wọ́n sì di ìránṣẹ́ òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí ìjọba* Páṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso,+ 21 kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ lè ṣẹ,+ títí ilẹ̀ náà fi san àwọn sábáàtì rẹ̀ tán.+ Ní gbogbo ọjọ́ tó fi wà ní ahoro, ó ń pa sábáàtì rẹ̀ mọ́, kí àádọ́rin (70) ọdún lè pé.+
-
-
Jeremáyà 25:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Gbogbo ilẹ̀ yìí á di àwókù àti ohun àríbẹ̀rù, àwọn orílẹ̀-èdè yìí á sì ní láti fi àádọ́rin (70) ọdún sin ọba Bábílónì.”’+
12 “‘Ṣùgbọ́n tí àádọ́rin (70) ọdún bá pé,+ màá pe ọba Bábílónì àti orílẹ̀-èdè yẹn wá jíhìn* nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’+ ni Jèhófà wí, ‘màá sì sọ ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà di ahoro títí láé.+
-