24 “‘“Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ́ ọba wọn,+ gbogbo wọn á sì ní olùṣọ́ àgùntàn kan.+ Wọ́n á máa tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọ́n á sì máa rí i pé àwọn ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+
5 Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì máa pa dà wá, wọ́n á wá Jèhófà Ọlọ́run wọn+ àti Dáfídì ọba wọn,+ wọ́n á sì gbọ̀n jìnnìjìnnì wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sí oore rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.+