Nehemáyà 12:27 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 27 Nígbà ayẹyẹ ṣíṣí ògiri Jerúsálẹ́mù, wọ́n wá àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerúsálẹ́mù láti gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ náà tayọ̀tayọ̀, pẹ̀lú orin ọpẹ́,+ pẹ̀lú síńbálì* àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù. Àìsáyà 44:28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 Ẹni tó ń sọ nípa Kírúsì+ pé, ‘Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi,Ó sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ délẹ̀délẹ̀’;+Ẹni tó ń sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘Wọ́n máa tún un kọ́’Àti nípa tẹ́ńpìlì pé, ‘Wọ́n máa fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.’”+ Jeremáyà 30:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, màá kó àwọn tó lọ sí oko ẹrú láti àgọ́ Jékọ́bù jọ,+Máa sì ṣojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀. Wọ́n á tún ìlú náà kọ́ sórí òkìtì rẹ̀,+Ibi tó sì yẹ ni wọ́n á kọ́ ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò sí.
27 Nígbà ayẹyẹ ṣíṣí ògiri Jerúsálẹ́mù, wọ́n wá àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerúsálẹ́mù láti gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ náà tayọ̀tayọ̀, pẹ̀lú orin ọpẹ́,+ pẹ̀lú síńbálì* àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù.
28 Ẹni tó ń sọ nípa Kírúsì+ pé, ‘Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi,Ó sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ délẹ̀délẹ̀’;+Ẹni tó ń sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘Wọ́n máa tún un kọ́’Àti nípa tẹ́ńpìlì pé, ‘Wọ́n máa fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.’”+
18 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Wò ó, màá kó àwọn tó lọ sí oko ẹrú láti àgọ́ Jékọ́bù jọ,+Máa sì ṣojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀. Wọ́n á tún ìlú náà kọ́ sórí òkìtì rẹ̀,+Ibi tó sì yẹ ni wọ́n á kọ́ ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò sí.