ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 36:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.

  • Nehemáyà 9:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+

  • Dáníẹ́lì 9:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+

  • Dáníẹ́lì 9:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Jèhófà, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo ìṣe òdodo rẹ,+ jọ̀ọ́, dáwọ́ ìbínú àti ìrunú rẹ dúró lórí ìlú rẹ, Jerúsálẹ́mù, òkè mímọ́ rẹ; torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣìṣe àwọn baba ńlá wa, gbogbo àwọn tó yí wa ká ń gan Jerúsálẹ́mù àti àwọn èèyàn rẹ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́