ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 26:38, 39
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Ẹ ó ṣègbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39 Àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú yín máa jẹrà sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín+ torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Àní, wọn yóò jẹrà dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn.+

  • 1 Àwọn Ọba 9:7-9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+

  • Sáàmù 79:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti ya wọnú ogún rẹ;+

      Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin;+

      Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di àwókù.+

  • Sáàmù 79:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;+

      Àwọn tó yí wa ká ń fi wá ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.

  • Jeremáyà 24:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Màá sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti àjálù lójú gbogbo ìjọba ayé,+ màá jẹ́ kí wọ́n di ẹni ẹ̀gàn àti ẹni àfipòwe, ẹni ẹ̀sín àti ẹni ègún + ní gbogbo ibi tí màá fọ́n wọn ká sí.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́