ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 5:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+

      Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba.

      Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+

      Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?”

  • Jeremáyà 14:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+

  • Míkà 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àwọn olórí* rẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó dájọ́,+

      Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń gba owó kí wọ́n tó kọ́ni,+

      Àwọn wòlíì rẹ̀ ń gba owó* kí wọ́n tó woṣẹ́.+

      Síbẹ̀ wọ́n gbára lé Jèhófà,* wọ́n ń sọ pé:

      “Ṣebí Jèhófà wà pẹ̀lú wa?+

      Àjálù kankan ò lè dé bá wa.”+

  • Sefanáyà 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+

      Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń sọ ohun mímọ́ di ẹlẹ́gbin;+

      Wọ́n ń rú òfin.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́