22 Ohun tí Olúwa rẹ, Jèhófà sọ nìyí, Ọlọ́run rẹ, tó ń gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀:
“Wò ó! Màá gba ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,+
Aago náà, ife ìbínú mi;
O ò ní mu ún mọ́ láé.+
23 Màá fi sí ọwọ́ àwọn tó ń dá ọ lóró,+
Àwọn tó sọ fún ọ pé, ‘Tẹ̀ ba ká lè rìn lórí rẹ!’
O wá sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀,
Bí ojú ọ̀nà tí wọ́n máa rìn kọjá.”