ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 26:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Èmi yóò mú kí idà pa àwọn ìlú yín,+ màá sì sọ àwọn ibi mímọ́ yín di ahoro, mi ò ní gbọ́ òórùn dídùn* àwọn ẹbọ yín.

  • Jeremáyà 26:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 nígbà náà, ńṣe ni màá ṣe ilé yìí bíi Ṣílò,+ màá sì sọ ìlú yìí di ibi ègún lójú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.’”’”+

  • Jeremáyà 52:12, 13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, ìyẹn, ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́, tó jẹ́ ẹmẹ̀wà* ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 13 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù; ó sì tún sun gbogbo ilé ńlá.

  • Ìsíkíẹ́lì 24:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 ‘Sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Mo máa tó sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ibi pàtàkì tí ẹ fi ń yangàn, tí ẹ fẹ́ràn gidigidi, tó sì máa ń wù yín.* Idà ni wọn yóò fi pa àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin tí ẹ fi sílẹ̀.+

  • Míkà 3:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Nítorí yín,

      Wọ́n á túlẹ̀ Síónì bíi pápá,

      Jerúsálẹ́mù á di àwókù,+

      Òkè Ilé* náà á sì dà bí àwọn ibi gíga nínú igbó.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́