53 O sì máa wá jẹ àwọn ọmọ* rẹ, ẹran ara àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ, torí bí nǹkan ṣe máa le tó nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti torí wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá ọ.
9 Màá sì mú kí wọ́n jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn, kálukú wọn á sì jẹ ẹran ara ọmọnìkejì rẹ̀, nítorí ogun tó dó tì wọ́n àti ìdààmú tó bá wọn nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn àti àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn há wọn mọ́.”’+
10 “‘“Ṣe ni àwọn bàbá tó wà ní àárín yín yóò jẹ àwọn ọmọ wọn,+ àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn bàbá wọn, màá ṣe ìdájọ́ yín, màá sì fọ́n àwọn tó ṣẹ́ kù nínú yín káàkiri.”’*+