-
Ẹ́sírà 9:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+
-
-
Jeremáyà 31:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Mo ti gbọ́ tí Éfúrémù ń kérora,
‘O ti tọ́ mi sọ́nà, mo sì ti gba ìtọ́sọ́nà,
Bí ọmọ màlúù tí a kò fi iṣẹ́ kọ́.
Mú mi pa dà, màá sì ṣe tán láti yí pa dà,
Nítorí ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run mi.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 6:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àwọn tó bá yè bọ́ yóò rántí mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó kó wọn lẹ́rú.+ Wọ́n á rí i pé ó dùn mí gan-an bí ọkàn àìṣòótọ́* wọn ṣe mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi+ àti bí ojú wọn ṣe mú kí ọkàn wọn fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.*+ Gbogbo iṣẹ́ ibi àtàwọn ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe yóò kó ìtìjú bá wọn, wọ́n á sì kórìíra rẹ̀ gidigidi.+
-