Ìsíkíẹ́lì 47:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Nígbà tí ọkùnrin náà jáde lọ sí apá ìlà oòrùn tó sì mú okùn ìdíwọ̀n dání,+ ó wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́,* ó sì mú mi gba inú omi náà; omi náà dé kókósẹ̀. Sekaráyà 2:1, 2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó mú okùn ìdíwọ̀n+ dání. 2 Torí náà, mo bi í pé: “Ibo lò ń lọ?” Ó fèsì pé: “Mo fẹ́ lọ wọn Jerúsálẹ́mù kí n lè mọ bó ṣe fẹ̀ tó àti bó ṣe gùn tó.”+ Ìfihàn 11:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 A sì fún mi ní esùsú* kan tó dà bí ọ̀pá*+ bó ṣe ń sọ pé: “Dìde, kí o wọn ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀. Ìfihàn 21:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá esùsú tí a fi wúrà ṣe dání kó lè fi ṣe ìwọ̀n, láti wọn ìlú náà àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ àti ògiri rẹ̀.+
3 Nígbà tí ọkùnrin náà jáde lọ sí apá ìlà oòrùn tó sì mú okùn ìdíwọ̀n dání,+ ó wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́,* ó sì mú mi gba inú omi náà; omi náà dé kókósẹ̀.
2 Mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó mú okùn ìdíwọ̀n+ dání. 2 Torí náà, mo bi í pé: “Ibo lò ń lọ?” Ó fèsì pé: “Mo fẹ́ lọ wọn Jerúsálẹ́mù kí n lè mọ bó ṣe fẹ̀ tó àti bó ṣe gùn tó.”+
11 A sì fún mi ní esùsú* kan tó dà bí ọ̀pá*+ bó ṣe ń sọ pé: “Dìde, kí o wọn ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀.
15 Ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá esùsú tí a fi wúrà ṣe dání kó lè fi ṣe ìwọ̀n, láti wọn ìlú náà àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ àti ògiri rẹ̀.+