16 Fèrèsé tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì+ wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ àti àwọn òpó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn nínú ẹnubodè náà. Fèrèsé tún wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ní inú ibi àbáwọlé ẹnu ọ̀nà náà, àwọn òpó tó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ní àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ lára.+