-
Nehemáyà 13:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó ti ṣètò yàrá ńlá kan tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* fún un, ibẹ̀ ni wọ́n máa ń kó ọrẹ ọkà sí tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú oje igi tùràrí àti àwọn nǹkan èlò, ibẹ̀ tún ni wọ́n ń kó ìdá mẹ́wàá ọkà, ti wáìnì tuntun àti ti òróró+ sí, èyí tó wà fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè, ibẹ̀ náà ni wọ́n sì ń kó ọrẹ tó wà fún àwọn àlùfáà sí.+
-