27 “‘Tí ẹnì kankan nínú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, tó ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe,+ tí ẹni náà sì jẹ̀bi, 28 tàbí tó wá mọ̀ pé òun ti ṣẹ̀, kó mú abo ọmọ ewúrẹ́ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá láti fi rú ẹbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.