ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nehemáyà 9:33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+

  • Jeremáyà 22:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 “‘Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú yìí, wọ́n á sì bi ara wọn pé: “Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?”+ 9 Wọ́n á fèsì pé: “Torí pé wọ́n fi májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń sìn wọ́n.”’+

  • Ìsíkíẹ́lì 9:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Torí náà, ó sọ fún mi pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ̀ gidigidi.+ Ìtàjẹ̀sílẹ̀ kún ilẹ̀ náà,+ ìwà ìbàjẹ́ sì kún ìlú náà.+ Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, Jèhófà ò sì rí wa.’+

  • Dáníẹ́lì 9:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́