-
Diutarónómì 29:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 àwọn àti gbogbo orílẹ̀-èdè máa sọ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí?+ Kí ló fa ìbínú tó le, tó kàmàmà yìí?’ 25 Wọ́n á wá sọ pé, ‘Torí pé wọ́n pa májẹ̀mú Jèhófà+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn tì ni, èyí tó bá wọn dá nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 26 Wọ́n lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn, àwọn ọlọ́run tí wọn ò mọ̀, tí kò sì gbà pé kí wọ́n máa jọ́sìn.*+
-
-
1 Àwọn Ọba 9:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
-