16 Tí o bá fetí sí àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí, tí ò ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí ò ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí o sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀, wàá máa wà láàyè,+ wàá sì máa pọ̀ sí i, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+