13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa fun ìwo ńlá kan,+ àwọn tó ń ṣègbé lọ ní ilẹ̀ Ásíríà+ àti àwọn tó fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì+ máa wá, wọ́n á sì forí balẹ̀ fún Jèhófà ní òkè mímọ́, ní Jerúsálẹ́mù.+
16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”